Waters of Life

Biblical Studies in Multiple Languages

Search in "Yoruba":
Home -- Yoruba -- The Ten Commandments -- 08 Fifth Commandment: Honor Your Father and Your Mother
This page in: -- Afrikaans -- Arabic -- Armenian -- Azeri -- Baoule? -- Bengali -- Bulgarian -- Cebuano -- Chinese -- English -- Farsi? -- Finnish? -- French -- German -- Gujarati -- Hebrew -- Hindi -- Hungarian? -- Indonesian -- Kiswahili -- Malayalam? -- Norwegian -- Polish -- Russian -- Serbian -- Spanish -- Tamil -- Turkish -- Twi -- Ukrainian? -- Urdu? -- Uzbek -- Yiddish -- YORUBA

Previous Lesson -- Next Lesson?

TOPIC 6: ÀWỌN ÒFIN MẸ́WÀÁ - Odíààbò Ọlọ́run tí ó ń pa Ènìyàn mọ kúró nínú Ìsubu
An Exposition of the Ten Commandments in Exodus 20 in the Light of the Gospel

08 - ÒFIN KẸFÀ: Má Ṣe Pànìyàń



ÉKÍSÓDÙ 20:13
“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn”


08.1 - Ìyàlẹ́nu Àmọ́ Òtítọ́

Ọkùnrin àkọ́kọ́ tí obìnrin bí tí bàbá rẹ̀ sì fẹ́fàn jẹ́ apànìyàn tí ó pa arákùnrin rẹ̀. Bíbélì ṣe àfihàn ọ̀ràn tí ó panilára àti ibajẹ tí ó gogo nínú ọkàn ènìyàn. Gbogbo ènìyàn ní ó ni èrò ìpànìyàn ní ọkan. Láti ìgbà tí Ádámù, ènìyàn ti ń gbé ní ìyapa sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń ṣe ìyangàn tí ó borí ìfẹ́ àti ìrètí rẹ̀. Ó rò nínú ara rẹ̀ wí pé òun ni ìwòye fún àwọn ẹlòmìíràn. Bí ẹnikan ba ṣe bí ẹni lágbára, ní òye, ìwà-bi Ọlọ́run tàbí rẹwà jù ú, ó lára rẹ á sì tún korìra rẹ̀. Ẹni kọ̀ọ̀kan ló fẹ̀ dàbí Ọlọ́run kékeré tí àwọn ẹlọ̀mìíràn yóò máa sìn. Ṣùgbọ́n ìgbéraga àti òdodo ara ẹni jẹ́ àwọn àbùdá tí ó le panilára.

Jésù pẹ̀ Esù ní “apànìyàn láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀” nítorí pé ó mú ènìyàn kúró ní ipò rẹ̀ níbi tí ó tí ní àjọọsepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Láti ìgbà yìí, ikú tí ní ipá lórí ènìyàn, “nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀”. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà padà sí òdò rẹ̀ nítorí ìfẹ́ àti ìdájọ́ rẹ̀. Gbogbo ẹni tí ó bá lo oorẹ ọ̀fé yìí, yóò yí ìgbàlà, tún ọkàn rẹ̀ ṣe kí ó sì gbà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn ayé rẹ̀ yóò gbà iye àìnípẹkun lọ́nìí. Èyí yóò sí fún ayé rẹ̀ ní ìtumọ̀.

Ènìyàn ní ọ̀pọ̀ èrò àti ìdí tí wọ́n fí ń pani. Jésù ṣe àfihàn rẹ̀ pé ìpànìyàn jẹ́ èrò àkókó nínú àwọn èrò búburú tí ó ń tí ọkàn ènìyàn jáde (Máttíù15:19). Ṣùgbọ́n ìjẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run lòdì sí èrò búburú tí ó ń tí ọkàn ènìyàn jáde, ó sì fẹ́ kí wọn pa òfin rẹ̀ mọ́ bí ó tí pá láṣẹ fún wọn, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa ènìyàn”. Fún ìdí èyí, gbogbo oríṣìí ọ̀nà ìgbẹ̀mí ara ẹni kódà ìpokùnso jẹ́ ohun tí ó lòdì sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run, a sì ribí ìlòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, tí ènìyàn bá ń ṣe búburú sí ẹlọ̀mìíràn láìbìkítà tí ebi bá ń pa wọ́n àti tí wọn kò sì kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn ewu tí ó mbọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú yóò jẹ́ apànìyàn. Tí ẹnikẹ́ni bá pa ènìyàn lára nípa fífi májèèlé sínú oúnjẹ tàbí rán ènìyàn lọ́wọ́ láti pa onítọ̀hún irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ni ìpín ní orí pẹpẹ ìdájọ́ kan náà pẹ̀lú àwọn apànìyàn ní ìdájọ́ ayérayé. Bí ènìyàn bá ṣe ẹnikejì ní ìjàmbá tí ó sì fa ìgekúrú ayé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ (Romu 13:1-18), onítọ̀hún jẹ́ apànìyàn. Ọlọ́run máa ń mú wa ṣe ìṣirò nípa ọmọlkejì wa kí àwa má ba yẹra kí a má sọ bí tí Káínì pé “Ṣe èmi jẹ́ alámòjútó arákùnrin mi?”


08.2 - Ìjìyà àti Ẹ̀san

Àmúrá ìdájọ́ ikú tí ó wà nínú májèmú láíláí wà fún gbígbé ogun ti apànìyàn àti agbénipa, kí a lè mú gbogbo òdodo ṣẹ (Ẹksodu 21:12,14,18). Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà tí ó ń pèsè ààbò fún ẹ̀mí wọn. Ìbèrù à ti lọ́wọ́ nínú ìjà ẹlẹ́yàmẹyàà tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀ tún jẹ́ ọ̀nà ààbò fún ẹnikọ̀ọ̀kan. Òfin “ojú fun ojú àti eyín fún eyín” jẹ́ kí á mọ irúfẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tọ́ fún iye ìjàmbá. Ṣùgbọ́n ìjìyà náà máa ń jẹ́ ìlọ́po fún ẹni tí ó bá pa olórí èyà. Lámékì bèèrè pè kí á gbà ẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rìn fún èrèdí pé wọ́n pa òun (Jénésíìsì 4:23-24). Irú ìṣesí yìí sì máa ń wáyé láàrìn àwọn ẹ̀yà kànkan nígbàkígbà tí wọ́n bá pa ọ̀kan lára àwọn olóríí wọn.

Ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní àforíjì nínú àṣà àwọn Júù, kò sì ní ètùtù ayafi ká ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀. Ìdáríjì á jẹ́ àìsòdodo. Àwọn ènìyàn máa ń ló ànfàni ìjérìíọkàn àwọn ẹlọ́mìíràn. Ìkórira ọ̀tá ń lọ láti ìran dé ìran bí ó tilẹ̀ jẹ́ láàrin orílẹ̀-èdè. Irú èrò yìí ṣe àjèjì sí àwọn onígbàgbọ́ yálà ní ìlà-oòrùn tàbí ní ìwò-oòrùn. Ìyípada dé bá àṣà yìí níwọ̀n ìgbàtí Jésù ti wẹ gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ ìpànìyàn kúrò.

Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà á di òtòṣì nítorí pé ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóò rì ín mọ́lẹ̀. Ẹ̀mí àwọn tí ó pa yóò máa dà á láàmú nínú èrò àti àláa rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, atamátàsé olóògùn kan rí tí agbárí àwọn tí ó ti pa ń yí bọ̀ wá báa, tí kòròfo ojúu wọn ń ranjú mọ́ọ pẹ̀lú. Lẹ́yìn ìran kan, ìrètí apànìyàn ni pé kí ọmọ́ àgbà ẹni tí ó ti parí pa òun náà pẹ̀lú, tí ó bá padà sí agboolé mùsùlùmí tí ó ti wá. Ìpànìyàn kò ní èrè, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀rùbànìyàn tàbí lílérí kòtó láti dẹ́kùn ìpànìyàn. A gbọ́dọ̀ yọ èrò ibi kúrò nínú ọkàn ènìyàn kí á sì fi èrò ọ̀tun dípò rẹ̀. Jésù mọ ìmíkanlẹ̀ ọkàn ènìyàn nínú èyí tí ó dá wa lẹ́jọ́ ìparun nígbà tí ó sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹni rere kan kò sí bíkòse ẹnikan, èyí ní Ọlọ́run” (Máttíù 19:17; Máàkù 10:18; Lúùkù 18:19). Ṣùgbọ́n lọ́nà kan náà, ó ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ sí ọkàn wa, nínú èyí tí a sọ ọkàn wa di tuntun, tí ó sì tún mú èrò ìpànìyàn kúrò nínú ọkàn wa. Jésù fún àwọn tí ó lè mú òfin rẹ̀ ṣẹ àti àwọn tí ó fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wọn ní ọkàn tuntun, ẹ̀mí ìdúró ṣinṣin, Ó sì sọ wọ́n di tirẹ̀.


08.3 - Èrò Onígbàgbọ́ nípa Ìpànìyàn àti Ìbálàjá

Nínú àwọn ẹ̀kọ̀ọ́ Jésù ní orí òkè, ó kọ́ wa wí pé, pípa àgọ̀ ara nìkan kọ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà, ṣùgbọ́n ìfẹnusáátá náà jẹ́ ìpànìyàn ní ẹ̀mí. Ó ní àtunbọ̀tán ọjọ́ iwájú bíi májèlé. Irúfẹ́ ọrọ̀ ìbàjẹ́, irọ́, ìkórira, ìdẹ́rùbà, ìgbóguntí, ó lè, èpè àmọ̀ọ́mọ̀ ssẹ́ tàbí ìfini ṣe ẹlẹ́yà léwu nípa tí ẹ̀mí. Wọ́n á kọ́kọ́ ṣe àkóbá fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́hìn náà wọ́n á tún ṣe àkóbá fún ọkàn ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn. Jésù wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bínú sí arákùnrin rẹ láì ní ìdí yóò wà ní ewu ìdájọ́.Síwájú síi, ẹni tí ó bá sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé “Ràkà!” yóò wà ní ewu ìgbìmò. Ṣùgbón ẹni tí ó bá wí pé, “Ìwọ aṣiwèrè!” yóò wà ní ewu ọ̀run àpádì (Máttíù 5:22). Nípa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù tí dá wa lébi tí ó sì tún dá wa lẹ́jọ́ bí ọlọ́kàn líle tí ó kún fún ibi tí ó ní ẹ̀mí ìpànìyàn, tí ó sì tún yẹ fún ọ̀run àpádì.

Ó yẹ kí á yíwàpadà kí á sì tún rí ara wa bí ènìyàn tí ó kún fún èrò ìpànìyàn. Ìbínú, ìlara, ìtẹramọ́ iṣẹ́ èdè àìyedè, ẹ̀mí owú, ẹ̀mí àìnídáríjì àti ìwà jàgídíjàgan jẹ́ ìmòlára àti iṣe tí tèwetàgbà máa ń ko jú. Abálájọ tí Jòhánnù fi sọ pé “ẹnikẹ́ni tí ó bá kórira arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn” (Jòhánnù Kìíní 3:15). A ní láti ṣe àyèwò fínní fínní láti ríi dájú pé a kò ní èrò ibi sí ènìyàn àti wí pé kí á bèèrè oorẹ ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run láti borí ẹ̀mí ìkórira pátápátá. Láì jẹ́ bẹ́ẹ̀ àwọn èrò ibi wọ̀nyí lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí wọ́n sì ṣe àkobá fún wa. Jésù ń retí kí gbogbo ẹni tí ó bá ń ka àdúrà Olúwa láti dáríjì gbogbo ènìyàn pátápátá bí Ọlọ́run ṣe dáríjì wá. Ọlọ́run ń retí kí á ní ẹ̀mí ìdáríjì. Akítíyàn wa àti inú wa láti dáríjì yóò mú wa borí àti láti ṣẹ́gun ìfẹ́ láti pa ọ̀tá wa run. A lè gbà láti dáríjì ọ̀tá, ṣùgbọ́n láìgbàgbé ẹ̀sùn wọn. Ṣọ́ra! Nípa èyí, ó dàbí ẹni pé a ń bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí ó dáríjì wá ṣùgbọ́n kí ó má gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wa. Tàbí kí á sọ wí pé “Mọ fẹ́ fi tinútinú dáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rẹ́ mi àti láti gbàgbé ẹ̀sùn rẹ̀ ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ríi mọ́!

Ṣé ó fẹ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n láì bá a pàdé tàbí ríi rárá? Ṣé ó fẹ́ kí ó hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hùwà sí ọ̀táa rẹ?

Jésù fí ọ̀nà kan sílẹ̀ fún wa láti ni àláàfíì, bí ó ṣe sọ, “Ẹ fẹ́ àwọn òtá yín. Ẹ sure fún àwọn ẹnití ó ń fi yín rẹ̀. Ẹ sóóré fún àwọn tí ó kórira yín, kí ẹ̀yin kí ó lè máa jẹ́ ọmọ Bàbá yín mbẹ ní ọ̀run” (Máttíù 5:44-45). Nípa agbára ìfẹ́ Ọlọ́run lá lè fí borí ẹ̀mí ìkórira èyí, tí ó wà nínú àwọn onírobìnújẹ́ ọkàn. Nítorí náà, Jésù ṣe ìkilọ̀ fún wa nípàtó pé; “Bí ẹ̀yin kò bá fí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́, Bàbá yín kì yóò sì fí ẹ̀ṣẹ̀ tí yín jì yín” (Máttíù 6:15).

Kí ni ìdí tí onígbàgbó fí gbọ́dọ̀ dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn òtá a wọn nígbàtí gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ kò gbọ́dọ̀ lọ láì jìyà? Ṣé àìsòdodo yìí kò ní lẹ́yìn? Dájúdájú! Ọlọ́run kò lè fojú fo ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Bí á tí ṣe kọ̀ọ́ wí pé, “láìsí ìtàjè sílẹ̀, kò lè sí ìmúkórò ẹ̀ṣẹ̀”. Fún ìdí èyí, Jésù kú fún wa, ó sì ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí pé “ṣùgbọ́n a ṣá a ní ọgbẹ́ nítórí ìrékọjá wa, a pa á ní ara nítorí àìsèdeédé wa, ìnà àlàáfíà wa wà lára rẹ̀, àti nípà ìnà rẹ̀ ní á fí mú wa lára dá” (Isaiah 53:5). Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run tí ó kú fún ẹ̀ṣẹ́ olóríjorí àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn afiniṣẹ̀sín pẹ̀lú àwọn apànìyàn. Èyí ló fún wa ní ànfàní láti dáríjì gbogbo ènìyàn láìsí àfi. A kò ní ẹ̀tọ́ tàbí ojúse láti ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ẹ̀san. Nínú ìjìyà àti ikú àgbàkú rẹ̀, gbogbo àmúyẹ ìdáláre tí Ọlọ́run ni Jésù mú ṣẹ. Òun ni àláàfíà wa. Ẹnikẹ́ni tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ rẹ tí ó sì tún ń wa ìdáláre fún ara rẹ̀, ń da ara rẹ lébi. Ìfẹ́ nìkan ni àkójá òfin. Fífà sẹ́yìn kúrò nínú ìfẹ́ túnmọ̀si fífi ọwọ́ ara ẹni fa ìdájọ́ lẹ́ẹ̀kansi. Jésù nìkan ni ó lè dá ọkàn túntún tí ó sílẹ̀ fí ìpinnu tuntun sí inú àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ ó sí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáríjì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ń dáríjì wá.


08.4 - Èsìn tí Ìdà

Gbogbo ènìyàn tí ó bá rí oorẹ ọ̀fẹ́ tí Jésù fún wa fún ìdájì yóò máa wòye ìdí tí Islam fí sọ pé ènìyàn gbọ́dọ̀ gbẹ́san ẹ̀jẹ̀. Ìjà mímọ́ pẹ̀lú ìmọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn jẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá ẹ̀sìn Islam. Islam fàyè gba ìpànìyàn nítorí ẹ̀sìn ó sì sọ́ di iṣẹ́ fún Mùsùlùmí. Mùhámọ́dù kọ nínú Kùránì “Mú wọn kí ó sì pa wọn níbikíbi tí ó bá rí wọn” kí “ó má sì ṣe yan ọ̀rẹ́ tàbí olùranlọ́wọ́ láàrín wọ́n” (Súràs al-Nisa 4:89,91 or al-Baqura 2:191). Ẹ̀mí Kírístì kò fàyè gba irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ṣùgbọ́n èmí tí “ìpànìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀”.

Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ní Mùhámọ́dù pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí ó sí darapọ̀ mọ́ ẹgbé métàdínlógbọ̀n tí ó ń dojú ìjà kọni. Ó tún gbà kí wọ́n gbẹ isàòkú fún àwọn Júù tí ó wà ní Mèdínà tí wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn nígbà ogun Khandaq.

Láti ìgbà ogun Badr, àwọn Mùsùlùmí tí ó bá pa ọ̀tá wọn nínú ogun mímọ́ ló ní ìdáláre nípa ọ̀rọ̀ Mùhámọ́dù wọ̀nyí, “Ẹ̀yin kọ́ ni o pa wo, ṣùgbọ́n Allah ni ó pa wọ́n. Ẹ̀yin kọ́ ni ó yin ìbọ, nígbà tí ẹyìn ín, ṣùgbọ́n Allah ni ó yìn ín” (Súrà al-Anfal 8:17). Èyí ni àwọn ajijaẹ̀sìn fí ń dá ara wọn láre ní ilé ẹjọ́ èyí tí kò dun mọ àwọn Mùsùlùmí kan nínú.Ìfihàn Mùhámọ́dù yìí ló fí ìdí idalare ìpànìyàn múlẹ̀ nígbà ogun mímọ́. Ní afihàn ẹnikẹ́ni tí ó bá kú nínú ogun Islam tí ó dojúkọ àwọn Kèfèrì ń lọ tààrà sí paradise, ibi tí yóò tí bá inú didun tí ara tí kò ṣe é ṣápèjúwe pàdé. Ṣùgbọ́n, òfin Islam kò fí ayegba kí àwọn Mùsùlùmí pa ara wọn láìni idi nítorí pé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ aláìniforíjì. Nípa èyí, àwọn aboríṣa àti gbogbo Kèfèrì kò ni ààbò kankan. Àwọn agbẹ̀mí pẹ̀lú jẹ́ oní-iṣẹ́-rere tí yóò rí èrè tí ó ti ọ̀run wa gbà. Láti inú onírúurú ìdájọ́ tí ó wà nínú òfin Islam láti rí èyí tí ó ṣe àjèjì sí wa. Ijẹ níya ńlá tí ẹni tí wọ́n gbà ẹ̀mí rẹ, al-dyia, lè rópò ìgbẹ́san. Ṣùgbọ́n ní ibi ìjàmbá ọkọ̀ àti ìfi ọkọ̀ gbá ọkọ̀, òfin ojú fún ojú, eyín fún eyín ń fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé yálà ó tọ́ sí òfin tàbí kò tọ́ sí òfin, ni àwọn ilẹ̀ tí òfin Islam ti tànkálẹ̀.

Nítorí pé ìdájọ́ tí ẹ̀sìn Islam ṣe ètò fún irú etùtù tirẹ̀, èyí tí ó ṣe ní dandan pé kí òtítọ́ àti ìdájọ́ kí ó múlẹ̀ láìsí àànú, kìí sábàá sí ààyé fún ṣiṣe iyèméjì tàbí kí ó má wáyé rárá. Àwọn Mùsùlùmí ò ní arọ́pò ẹni tàbí àgùntàn Ọlọ́run tí ó fi ìràpadà ayérayé kalẹ̀. Wọn kò ní ìmọ̀ nípa oorẹ ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó borí gbogbo ìfẹ́ òtítọ́. Nítorí náà wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ìdájọ́ láìsí oorẹ ọ̀fẹ́.


08.5 - Ìwàásù lórí òkè lòdì sí Jihad

Ìgbé ayé e tí májèmù láìláì dá lórí ìdájọ́. Òfin Mose tankalẹ̀ gbogbo igbé ayé ènìyàn, kò sí ń ṣe òfin tí ìlú nìkan ṣùgbọ́n tí ètọ̀ ẹ̀sìn pẹ̀lú. Báyìí àwọn ìdárí ẹsìn tí ìlú aní láti ṣe sisan ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó lòdì sí òfin ní dandan. Ìjà ẹ̀sìn jẹ́ àbájádé tí májẹ̀mú láíláí àìleyẹsílẹ̀ àti ìmọ̀ òfin Islam àti ètò ìsèlú. Gbogbo ìjà ẹ̀sin kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gba ní iwájú Ọlọ́run mọ láti ìgbà tí Jésù Kírísítì tí wàásù wí pé kí gbogbo ènìyàn fẹ́ràn ọ̀tá wọn kí wọ́n sì tún má hùwà rẹ̀. Ogun tí àwọn onígbàgbọ́ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìfásẹ́yìn nípa ṣíṣẹ̀ ayewo ìbátan ẹ̀sìn sí ìdárí tí ṣíṣà koso ìlú. Jésù kò ran àwọn Àpòstẹ́lì rẹ láti lọ wàásù ìhinrere nínú ayé pẹ̀lú ìdà. Dípò èyí, ó wí fún Pétérù pé, “fi ìdà rẹ sí ipò rẹ̀, nítorí pé gbogbo àwọn tí ó bá mú ìdà ni yóò tí ipa ìdà sègbé” (Máttíù 26:52). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Jésù jẹ́ olódodo, ó fí tìfẹ́tìfẹ́ lọ sí orí igi agbélébùú tí ó sì kú, ó sí tún kọ̀ láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun áńgẹ́lì. Ẹ̀mí Krístì lòdì pátápátá sí Ẹ̀mí Mùhámọ́dù. Jésù wí nínú ìwàásù rẹ̀ lórí òkè pé “Ẹ̀yin tí gbọ́ bí á tí wí pé ojú fún ojú, eyín fún eyín. Ṣùgbọ́n èmí wí fún yín ẹ máṣe kọ ibi. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbá ó ní èrèké òtún, yí ti òsì síi pẹ̀lú” (Máttíù 5:38-39). Báyìí, Jésù borí ibẹ́ ayé àtìjọ́ tí máa ń fẹ gbẹ̀san. Àìlera ìkáàárẹ̀ ní àgọ́ ara Krístì ní orí agbélébùú àti agbára ẹ̀mí rẹ̀, tíí ó ṣe ìfẹ́ ìgbàgbọ́ àti ìrètí jẹ́ ọ̀nà kanṣoṣo láti borí èṣu àti láti mú gbogbo ìfẹ́ òfin àtòrun wá ṣẹ. Onígbàgbọ́ máa ń dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbèèrè bíi: kí ni mọ lè ṣe nígbà tí a bá fí agbára mú mi tí a sì pọ̀n ọ́n ní dandan láti ló ohun ìjà lójú ogun? Kí ní èyí jásí fún onígbàgbọ́ ní orílẹ̀-èdè ńlá tàbí fún àwọn onígbàgbọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn onígbàgbọ́ tí kéré níye? Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà sẹ́yìn, àwọn onígbàgbọ́ ní onírúurú ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè tó lójú yìí.Àwọn arákùnrin kan ṣetán láti fí ara dá túbú, kí wọ́n sì kú gẹ́gẹ́ bíi Martyrs nítorí ẹrí ìgbàgbọ́ wọn nínú Kírísítì.

Àwọn mìíràn fẹ́ láti gbọ́ràn sí àṣẹ ìjọba tí Ọlọ́run yàn lé wọn lórí. Wọ́n ka òfin tí ó lòdì sí ìpànìyàn sí ogun àdájà fún oníkálukú. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn kò kórira ẹnikẹ́ni àwọn ọ̀tá wọn àti láti sòtítọ́ sí ìjọba orílẹ̀-èdè wọn bákanáà. Wọ́n ka ìjọba Ọlọ́run tí ó mbò sí ìjọba ayérayé, wọ́n sì tẹ́wọ́gba ìjọba ayé yìí gẹ́gẹ́ bíi kò ṣe é manìí tàbí tí ó pọ̀n dándan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìṣòro pẹ̀lú àwọn ìbèèrè yìí yóò wá ojú Ọlọ́run nítòótọ́. Á rí ojútuú sí àwọn ìbèèrè yìí. Ṣùgbọ́n, irú àwọn onígbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ní láti ṣọ́ra kí wọ́n máa bá fojú témmbẹ́lú àwọn tí wọ́n ṣe ìpinnu òdì. Ojúṣe fún orílẹ̀-èdè ẹni tàbí ìlú pẹ̀lú jẹ́ òfin Ọlọ́run bíi fífẹ́ tá ẹni.


08.6 - Apànìyàn Òde Òní

Ìwàásù orí òkè, èyí tí ó kún fún apèjúwe ìjọba ọ̀run lábẹ́ májẹ̀mú tuntun lè sé ẹ ṣé fún ènìyàn. Ó tí ẹ̀ jọ bí ẹni pé àkókò kòìtó láti mú lò pẹ̀lú òṣẹ̀lú. Bí ènìyàn bá ń gbìyànjú láti wá àláàfíà pẹ̀lú jàgídíjagan –an, ó fi hàn pé òye ìwàásù orí òkè kò yé onítòhún, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó fọwọ́ sí ogún ṣiṣẹ́ ní àgbálá ayé. Ẹlẹ́yìí gan ni ìwà ọ̀daràn tí ó buru jù lọ̀ tí ènìyàn tí ṣe nínú ìtàn. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù afọ̀ tí ó ń gbé inú ni wọ́n ṣẹ́ dànù. ọ̀pọ̀ bàbá àti ìyá ni ó ń gbé ẹ̀rí ọkàn àpànìyàn. À ń gbé nínú ìran àwọn apànìyàn ní àìmọ̀pé a jẹ́ ara ìran náà.

Ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún ènìyàn ló lọ́wọ́ sí ìjàmbá ọkọ̀, kìí ṣe tí àṣìṣe tàbí ojú ẹ̀ro ìgbàlódé, ṣùgbọ́n, nítorí ìmutípara, síṣaré kọja àlà tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì. Tí á bá fẹ́ pa òfin kẹfa mọ, ó yẹ kí a rí ìjàmbá ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìpànìyàn àti kí a sí yí bí a tí ń wa ọkọ̀ padà. A nílọ̀ láti wa ọkọ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ìkóra ẹni-ní-jànu, wíwá ààbò Ọlọ́run àti kí a sì bèrè fún ìrẹ̀lẹ̀. À ń gbé ni ìgbà tí agbégbe kún fún èérí, nígbà tí afẹ́fẹ́, omi àti oúnjẹ ń ní májèlé. Bóyá ìjìyà Ọlọ́run lè dínkù bí a bá fẹ́ràn agbegbé tó yí wa ká, kí a sì gbé ojú wa sókè sí Ọlọ́run kí a sì má bèèrè bí a ṣe lè gbé lọ́nà tó tọ́. lónà yìí à ń ṣe ìtọju àgbáyé wa a sì ń gbìyànjú láti má bàájẹ fún ra wa.

Àjẹjù tún jẹ́ ìpànìyàn tó farasìn tí ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn ní ìgbé ayé ìrọ̀rùn ní àwùjọ ń gbà láàyè, wọ́n sì ń pa ara wọn díẹ̀díẹ̀. Àwọn ń gbà iṣekúṣe láàyè wọ́n sì ń pa ara, ọkàn àti ẹ̀mí wọn.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jowu tàbí jẹ́ onímọ̀ tara ẹni nìkan ń jìyà lọ́wọ́ ìrònú àti àdánikan wà tí yóò sì gé ayé rẹ̀ kúrú. Bákan náà, iṣẹ́ àṣejù, àìnísinmi àti ìbáraẹnijẹ lè pani lára fúnra wọn. Àìsùn déédéé àti ìgbèayé tí ó ń yọ̀ jẹ́ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ara nítorí Ọlọ́run ló ni wa kìí ṣe ara wa.

Jésù kọ́ wa ní ìséraẹni kìí ṣe irura-ẹni-sókè nígbà tí ó sọ pé “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà ẹ̀mí ara rẹ̀ la, yóò sọ ọ nù; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi yóò ríi” (Máttíù 16:25). Páùlù tẹnumọ pé “Ìjọba Ọlọ́run kìí ṣe fún jijẹ àti mimú ṣùgbọ́n ododo àti àláàfíà pẹ̀lú ayọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́” (Rom 14:17). Ìgbé ayé ẹ̀mí tí ó lọ déédéé máa ń mú ìgbè ayé tí ara tí ó ni àláàfíà ọkàn àti inú.

Òfin kẹfà kò fàye gbà oríṣìíríṣìí ìpànìyàn ó sì rọ̀ wá nígbà kan náà pé kí a máa ṣe rere nínú ìfẹ́. Ó gbìyànjú láti jì ìbákedun nínú wa fún àwọn tí ó ń gbé nínú ìṣẹ́. A kò gbọ́dọ̀ gbà ẹ̀gbẹ́ aláìní kọjá bí ẹni pé a kò ríi, ṣùgbọ́n kí á fún-un ní àyè kí a sì ràn-án lọ́wọ́ ní kíá kíá. Jésù, ara kan náà pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, fihàn wá bí a ṣe lè ṣe sọ́nà bí a bá bèrè fún ọgbọ́n. Jésù nìkan ló lè yí àwọn apànìyàn padà sí ọmọ ìfẹ́ rẹ̀ kí ó sì rànán wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àwọn tó ń ṣe àìsàn nínú ẹ̀mí náà. Èyí yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá fi wọ́n hàn oluwòsàn gbogbo àwọn oluwòsàn. Jésù tí ó máa ń tún wọn dá tí ó sì máa ń ṣe wẹ̀nùmọ́ wọn láti mú kí ó sì yí àwọn ẹ̀mí apànìyàn padà sí ẹni tó ń sìn àti olùfẹ́.

www.Waters-of-Life.net

Page last modified on March 18, 2014, at 09:17 AM | powered by PmWiki (pmwiki-2.3.3)